Kòsí ìdánwò lọ́jọ́ ọdún o

Ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìdánwò  lórílẹ̀-èdè ,(NECO), sọ pé àwọn kò  ṣètò ìdánwò èyíkéyìí fún ọjọ́ Àbáméta,ọjọ́ kẹsàn án, Oṣù Keje,ọdún 2022 nínú  ìdánwò oníwèé ẹ̀rí Ilé-ìwé gíga tí ń lọ lọ́wọ́ (SSCE), fún àwọn olùdíje tí ó wà ní ilé-ìwé. Igbimọ idanwo naa sọ pe oun ko lọwọ ninu awuyewuye to n lọ lọwọ […]

Kòsí ìdánwò lọ́jọ́ ọdún o

Ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìdánwò  lórílẹ̀-èdè ,(NECO), sọ pé àwọn kò  ṣètò ìdánwò èyíkéyìí fún ọjọ́ Àbáméta,ọjọ́ kẹsàn án, Oṣù Keje,ọdún 2022 nínú  ìdánwò oníwèé ẹ̀rí Ilé-ìwé gíga tí ń lọ lọ́wọ́ (SSCE), fún àwọn olùdíje tí ó wà ní ilé-ìwé.

Igbimọ idanwo naa sọ pe oun ko lọwọ ninu awuyewuye to n lọ lọwọ lori pe Igbimọ naa ṣeto idanwo fun ọjọ kẹsan an, Oṣu Keje, ọdun 2022, eyiti o jẹ Ọjọ ọdun ileya (Eid-Al-Adha).

Atẹjade kan ni Ọjọ Aje,ọga agba fun ibaraẹnisọrọ  ati ajọṣepọ ikọ,NECO, Azeez Sani, sọ pe Igbimọ naa mọ pataki  awọn ajọdun ẹsin ti  o si maa n pese eto to peye nigbagbogbo  fun iru bẹ ni ṣiṣatunṣe awọn ọjọ idanwo.

A yoo ranti pe Idanwo Iwe-ẹri Ile-iwe giga ti ọdun 2022 ,(SSCE) fun Awọn oludije ti o ṣi wa  nile-iwe ti bẹrẹ ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, Oṣu kẹfa, ti  yoo si pari ni ọjọ kejila, Oṣu Kẹjọ, 2022.