Iyabo Ojo: Ojú ọkọ mi ní àwọn adigunjalè ti fipá bá mi lòpọ̀ ní ìgbà karùn-ún

0
199

Gbajugbaja oṣere, Iyabo Ojo sọ iriri rẹ nigba bi wọn ṣe fi ipa ba a lọpọ ni igba marun un nigba ti o wa ni kekere titi to fi di abilekọ.

Oju opo Instagram rẹ ni Iyabo Ojo ti sọ iriri rẹ naa, eyi to pe ni ”Bare it With IY” lori ayelujara.

Iyabo Ojo ni igba akọkọ ti wọn fi ipa ba oun lopọ ni igba ti oun jẹ ọmọ ọdun mẹrinla.

Ọmọ ọdun mẹrinla ni mi nigba ti wọn kọkọ fi ipa bamilopọ

O ni oun ti dakẹ lori iṣẹlẹ naa fun ọpọlọpọ ọdun nitori oun ko fẹ ki awọn eniyan sọrọ tako oun ni awujọ.

”Mo mọ ọpọlọpọ obinrin ti wọn ti ni idojukọ yii amọ wọn ko le sọrọ nipa ẹ nitori ibẹru pe ki ni awọn eniyan yoo sọ nipa ẹ, amọ o dara ki awọn eniyan sọrọ nipa awọn iṣẹlẹ to n la kọja.”

”Igba akọkọ ti isẹlẹ yii yoo waye nigba ti mo n gbe ni ile anti mi, nitori emi ni mo ṣi ilẹkun fun ẹni ọhun, ni mo si gba ko wọle amọ mi o mọ pe nkan ti yoo ṣe niyẹn”

Iyabo Ojo

”Amọ nigba to fi ipa ba mi lopọ tan, mo bẹru ẹni naa nitori o fẹ pa mi, o si tun un bẹmi, nitori naa, mi o le sọ fun ẹnikẹni”.

”Ẹlẹẹkeji naa ṣẹlẹ ni inu ile wa, ti mi o si le sọrọ nipa ẹ fun awọn ẹbi wa nitori ọpọlọpọ nnkan lo ṣẹlẹ”.

”Igba kan mo ti lẹ salọ kuro ni ile ti awọn obi mi bẹrẹ si ni wani, amọ ọrẹ mi nikan ni mo sọfun nigba naa.”

Ọrẹ si ọrẹkunrin mi lo fi ipa bamilopọ ni igba kẹrin pẹlu ọbẹ lọwọ

”Lẹyin naa ni igba ti mo jẹ ẹni ọdun mejidinlogun ti ọrẹ si ọrẹkunrin mi fi ipa ba mi lopọ”

”Mo n lọ lọna, ni mo ri i ninu mọto ayọkẹlẹ rẹ nitori agbegbe kan naa ni a jọ n gbe tẹlẹ, ki wọn to kuro ni agbegbe naa”

”O sọ fun mi pe oun n lọ si agbegbe Ikẹja ti emi naa n lọ, ati pe ni agbegbe kan naa ni.”

Iyabo Ojo

”Nigba ti a wọ inu ọkọ rẹ lo ni oun yoo gbe mi lọ ile oun, ti mi o si mọ nkan to wa ninu rẹ.”

”Lẹyin igba ta de ile rẹ lo ṣe ounjẹ fun mi, ti mo si sọ wi pe mi o fẹ amọ o bẹrẹ si fi si mi lẹnu.”

Iyabọ Ojo ni arakunrin naa bẹrẹ si ni sọ ọrọ ifẹ si oun, ati wi pe oun ti fẹran rẹ, ki ọrẹkunrin oun to bẹrẹ si ni fẹran oun.

Iyabọ ni oun ja fatafata nigba ti ọkunrin naa bẹrẹ si ni fi ọwọ kan oun, to si di ọrun oun mu

Lẹyin naa lo gba oju oun, to si lọ mu ọbẹ ko to di wi pe oun fi ara oun silẹ, ti oun si gba laaye lati ba oun lọpọ”

O bẹrẹ si ni bẹ mi lẹyin naa pẹlu ọbẹ lọwọ, amọ oun pẹtu si, ki oun fi le jade kuro nibẹ.

Nigba ti mo jade tan, mo de ile mo si bẹrẹ si ni sọkun nitori mi o le sọ fun ọrẹkunrin mi to jẹ ọrẹ rẹ nitori o le lọ pa a.

Awọn adigunjale ti wọn sa ọkọ mi ni ada lori lo fi ipa bamilopọ ni igba karun un.

Igba karun ni igba ti mo ti ni ọkọ pẹlu ọmọ meji ti awọn adigunjale wa si ile wa”

Wọn sa ọkọ mi ni ada lori, ti ẹjẹ si tu jade ni ori ọkọ mi, mo ro wipe ọkọ mi ti ku nitori ẹjẹ to n san ti pọju.

Lẹyin naa ni awọn adigunjale naa na mi, ti wọn si da egbo si mi lara nitori ọpọlọpọ ipalara ati iya ti wọn fi jẹ mi.

Lẹyin ti wọn ko gbogbo owo, goolu ati awọn ohun ini ti a ni si inu ile, ni ọkan ninu wọn tun pada wa si ibi ti mo dubulẹ si, ti wọn ti na mi”

O ya gbogbo aṣọ mi, o si tun fi ipa ba mi lopọ nibẹ.

Gbajugbaja osere naa to sọ iriri rẹ ni oun wa parọwa si awọn eniyan ti wọn n la iru iṣẹlẹ yii kọja lati maṣe dakẹ, ki wọn sọrọ si ita nitori egbo ayeraye ti kii san ni.

Iyabo Ojo wa parọwa si awọn obinrin ti wọn ti fi tipa ba lopọ lati lọ fun iwosan to yẹ nitori awọn obinrin miran ma n ni arun ọpọlọ nitori iwa ifipabanilopọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.