Igbákejì ààrẹ Ọ̀ṣínbàjò ń darí àpèjọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ àpapọ̀

Ìpàdé ọlọ́sẹ̀ẹ̀sẹ̀ Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ àpapọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ní gbọ̀ngàn ìgbìmọ̀, ní Víllà, Àbújá, pẹ̀lú Igbákejì Ààrẹ Yẹmí Ọ̀ṣínbàjò. Ọjọgbọn Ọṣinbajo lo n dari ipade naa nigba ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti lọ si orilẹ-ede Pọtugali lati lọ jẹ ipe Aarẹ Marcelo Rebelo de Sousa. Akọwe ijọba apapọ, Ọgbẹni Boss Mustapha; ati Ọga agba fun awọn […]

Igbákejì ààrẹ Ọ̀ṣínbàjò ń darí àpèjọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ àpapọ̀

Ìpàdé ọlọ́sẹ̀ẹ̀sẹ̀ Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ àpapọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ní gbọ̀ngàn ìgbìmọ̀, ní Víllà, Àbújá, pẹ̀lú Igbákejì Ààrẹ Yẹmí Ọ̀ṣínbàjò.

Ọjọgbọn Ọṣinbajo lo n dari ipade naa nigba ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti lọ si orilẹ-ede Pọtugali lati lọ jẹ ipe Aarẹ Marcelo Rebelo de Sousa.

Akọwe ijọba apapọ, Ọgbẹni Boss Mustapha; ati Ọga agba fun awọn Oṣiṣẹ  Aarẹ, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari, wa nibi ipade naa.

Awon minisita to wa nibi ipade naa ni: Iṣẹ ati Ibugbe, Babatunde Fashọla; Adajọ, Abubakar Malami; Isuna, Inawo ati Eto Orilẹ-ede, Zainab Ahmed; Iṣẹ ṣiṣe, Chris Ngige; ati Ibaraẹnisọrọ ọrọ-aje ayelujara , Isa Pantami.

Awọn minisita miiran to yun wa nibi ipade naa ni: ti Iṣẹ-ọgbin ati Idagbasoke igberiko, Mohammad Abubakar; Ayika, Mohammed Abdullahi; ati Ilera, Osagie Ehanire.

Minisita ipinlẹ fun Isuna ati  Eto Orilẹ-ede, Clem Agba; ati minisita ipinlẹ fun eto ilera, Adeleke Mamora tun wa nibi ipade naa.

Alaye lẹkunrẹrẹ nigbamii…