Ètò Ààbò: Ẹ ṣeun ẹkú àtìlẹ́yìn wa – Ọrílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọrílẹ̀-èdè Portugal bẹ́ẹ̀

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti fi ìmọrírì hàn sí orílẹ̀-èdè Portugal fún bí wọ́n ṣe kó ohun ìjà fún wa àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ ológun láti rí i dájú pé àlàáfíà wà ní ẹkùn Ìwọ̀ Oòrùn àti Àárín Gbùngbùn Áfíríkà. Nígbàtí ó ń sọ̀rọ̀ ní àsìkò oúnjẹ alẹ́ ní ààfin Ìpínlẹ̀ ní Ajuda, Lisbon, olú-ìlú Portugal […]

Ètò Ààbò: Ẹ ṣeun ẹkú àtìlẹ́yìn wa – Ọrílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọrílẹ̀-èdè Portugal bẹ́ẹ̀

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti fi ìmọrírì hàn sí orílẹ̀-èdè Portugal fún bí wọ́n ṣe kó ohun ìjà fún wa àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ ológun láti rí i dájú pé àlàáfíà wà ní ẹkùn Ìwọ̀ Oòrùn àti Àárín Gbùngbùn Áfíríkà.

Nígbàtí ó ń sọ̀rọ̀ ní àsìkò oúnjẹ alẹ́ ní ààfin Ìpínlẹ̀ ní Ajuda, Lisbon, olú-ìlú Portugal ní alẹ́ ọjọ́bọ̀, Ààrẹ yin olùgbàlejò rẹ̀, Ààrẹ Marcelo Rebelo de Sousa fún rírán àwọn ọmọ-ogun fún àlàáfíà sí Àárín Gbùngbùn Áfíríkà, mímójútó àwọn ìdàgbàsókè òṣèlú àti pípèsè ìrànlọ́wọ́ sí àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà, bíi Equatorial Guinea, Cape Verde àti Mozambique.

Ọláyinká Akíntọ́lá.