Aṣòfin Gbàjàbíàmílà jẹ́ ẹni àmúyangàn ní Èkó- Ilé Aṣòfin Èkó

Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ati awọn ọmọ ẹgbẹ yooku ti gboriyin loriṣiriṣi fun Aṣofin Fẹmi Gbajabiamila ti o jẹ Oludari Ile Igbimọ Aṣojuṣofin orilẹ-ede Niaijiria fun ti ọjọ ibi ọgọta ọdun rẹ laye. Awọn ọmọ Ile Aṣofin Eko ṣapejuwe Aṣofin Gbajabiamila gẹgẹ bi ẹni amuyangan ni Ipinlẹ Eko. Aṣofin Mudashiru […]

Aṣòfin Gbàjàbíàmílà jẹ́ ẹni àmúyangàn ní Èkó- Ilé Aṣòfin Èkó

Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ati awọn ọmọ ẹgbẹ yooku ti gboriyin loriṣiriṣi fun Aṣofin Fẹmi Gbajabiamila ti o jẹ Oludari Ile Igbimọ Aṣojuṣofin orilẹ-ede Niaijiria fun ti ọjọ ibi ọgọta ọdun rẹ laye.
Awọn ọmọ Ile Aṣofin Eko ṣapejuwe Aṣofin Gbajabiamila gẹgẹ bi ẹni amuyangan ni Ipinlẹ Eko.
Aṣofin Mudashiru Ọbasa ṣapejuwe Aṣofin Gbajabiamila gẹgẹ bi aṣofin to fi gbogbo ara ṣiṣẹ pẹlu ifẹ ọkan. Ẹni to fi gbogbo ara jin paapaa fun ifẹ awọn ara ilu. O ni:
“Bẹẹ ba ranti ni asiko ijọba ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), ijọba fi oye ilu da a lọla, ṣugbọn gẹgẹ bi ẹni to mọ ohun to n ṣe, ti o si ri ọwọ ti wọn fi n mu iṣakoso ilu ni asiko naa, o kọ oye ibọla-fun-ni naa.”
“Eleyii fi han pe o jẹ ẹni ti ifẹ ara ilu jẹ logun, ti o si ṣe tan lati sin wọn. Bakan naa ni o ti kopa to nitumọ ninu idagbasoke iṣẹ aṣofin lorilẹ-ede yii.
Oludari Ile naa wa paṣẹ fun Akọwe-agba Ile, Amofin Ọlalekan Ọnafẹkọ lati fi iwe ikini-ku-oriire ranṣe si Aṣofin Gbajabiamila fun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ, lorukọ Ile Aṣofin Eko.
Ninu ọrọ rẹ, Igbakeji Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Wasiu Ẹshinlokun-Sanni ṣapejuwe Aṣofin Gbajabiamila gẹgẹ bi Aṣofin tootọ ti wọn fi n gbadura fun ipo aṣofin. O ni:
“O ti fi han pe iriri ṣagba ọgbọn, nitori bi o ti pẹ ninu Ile Aṣofin naa to,̣ ni o n jẹ ki iṣẹ rẹ dantọ sii”
Olori ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ julọ ninu Ile Aṣofin Eko, Aṣofin Sanai Agunbiade ṣapejuwe Aṣofin Gbajabiamila gẹgẹ bi ẹni ti o ni abuda ara ọtọ fun iṣẹ aṣofin to n ṣe. O ni:
“O jẹ ẹni to fara balẹ lẹnu iṣẹ. Ni ọpọ igba ti o ba n dari ile, waa mọ pe o kọṣẹmọṣẹ naa.”
Bakan naa, Igbakeji Akoninijanu Ile, Aṣofin Mosunmola Sangodara ti o wa lati ẹkun Idibo Aṣofin agba naa, ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi oloṣelu nla, ti o ti mu ọpọ idagbasoke wọ ẹkun Surulere.
Bakan naa, Aṣofin Temitọpẹ, Aṣofin Aṣofin Olumọ ati awọn miiran gboriyin fun iṣẹ takuntakun Aṣofin Gbajabiamila, ti wọn si ki i ku oriire ọjọ ibi rẹ, pe yoo ṣọpọ rẹ laye. ̣
Ẹwẹ, ninu Gbọngan Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko lọjọ naa ni awọn aṣofin kan ti fi ehonu han si bi eto idibo abẹle to kọja ni Ipinlẹ Eko ko ṣe tọ, paapaa ti atubotan rẹ ko ṣe jẹ ki ọpọ wọn pada si Ile naa fun saa to n bọ. Lara awọn to fẹdun ọkan han bayii ni Aṣofin Victor Akande, Aṣofin Rotimi Olowo. Wọn ṣalaye pe ki wọn ṣatunṣe si ilana naa nitori ọjọ iwaju.