A kò kóóríra ẹ̀sìn kankan o

Ìjọba Nàìjíríà sọ pé àwọn òfin àti ìlànà orílẹ̀-èdè kò  fàyègba èyíkéyìí irú  òfin ẹ̀sìn tàbí inúnibíni ẹ̀sìn. Minisita fun eto ibaraẹnisọrọ ati Aṣa,Lai Muhammad sọ eyi nibi ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Voice of Naijiria,VON ni Ilu Lọndọnu, ni ọjọ Aje,lara awọn eto to to jọ fun irin-ajo ifọrọwọrọ ọdọọdun agbaye rẹ ati  ‘Think-Tank Engagement’. Minisita naa […]

A kò kóóríra ẹ̀sìn kankan o

Ìjọba Nàìjíríà sọ pé àwọn òfin àti ìlànà orílẹ̀-èdè kò  fàyègba èyíkéyìí irú  òfin ẹ̀sìn tàbí inúnibíni ẹ̀sìn.

Minisita fun eto ibaraẹnisọrọ ati Aṣa,Lai Muhammad sọ eyi nibi ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Voice of Naijiria,VON ni Ilu Lọndọnu, ni ọjọ Aje,lara awọn eto to to jọ fun irin-ajo ifọrọwọrọ ọdọọdun agbaye rẹ ati  ‘Think-Tank Engagement’.

Minisita naa ṣalaye yii lati fihan pe oun lodi si lẹta kan ti awọn Sẹnatọ ile-igbimọ Amẹrika marun kan kọ si Akọwe orilẹ-ede, Anthony Blinken,ti o rọ ijọba AMẸRIKA lati fi orilẹ-ede Naijiria kun  awọn orilẹ-ede ti awọn Kristiani ti dojukọ laasigbo inunibini  ẹsin.

Fun idi eyi,ijọba orilẹ-ede Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu ipe ti awọn Aṣofin ile-igbimọ Amẹrika marun-un naa pe, ti n beere fun dida orilẹ-ede Naijiria pada si orilẹ-ede to nilo agbeyẹwo pataki nitori inunibini si awọn Kristiani