Àwọn Ògbóùntarìgì òṣèré Nàìjíríà Darapọ mọ Oscars

Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Oscars fún àwọn òṣèré  àti  ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ńsì ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ṣàfihàn tí ó sì tún  fìwé pe àwọn òṣèré / Àwọn tó ń ṣètò eré ní Nàìjíríà: Fúnkẹ́ Akíndélé-Béllò, Daniel K. Daniel, àti Blessing Egbe láti kópa nínú ìlànà ìdìbò Oscars tí ń bọ̀. Oṣere ati oludari ere Funke Akindele-Bello ti wọn pe […]

Àwọn Ògbóùntarìgì òṣèré Nàìjíríà Darapọ mọ Oscars

Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Oscars fún àwọn òṣèré  àti  ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ńsì ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ṣàfihàn tí ó sì tún  fìwé pe àwọn òṣèré / Àwọn tó ń ṣètò eré ní Nàìjíríà: Fúnkẹ́ Akíndélé-Béllò, Daniel K. Daniel, àti Blessing Egbe láti kópa nínú ìlànà ìdìbò Oscars tí ń bọ̀.

Blessing Egbe, Daniel K. Daniel, Funke Akindele-Bello

Oṣere ati oludari ere Funke Akindele-Bello ti wọn pe ni ẹka iṣere fun aṣeyọri rẹ lori ‘Omo Ghetto: Fiimu ‘The Saga’ , oṣere ti o gbe ni AMẸRIKA Daniel K. Daniel tun wa ni ẹka oṣere fun fiimu ‘The Fugitive’ ati ‘A Soldier’s Story’, ati Blessing Effiom Egbe, ti oun naa fakọyọ  ninu atokọ oludari fun ‘African Messiah’ ati ‘Iquo’s Journal,’ yoo kopa ninu yiyan Oscars ati ilana idibo lati mu awọn to ba yege .

Awọn oṣere tuntun  Naijiria n darapọ mọ ọpọlọpọ awọn aṣoju ti n ṣiṣẹ bi ọmọ ẹgbẹ fun Ile-ẹkọ giga naa.

Ni ọdun to kọja, Ile-ẹkọ giga gba Ramsey Nouah Jr., Mo Abudu ati oludari kan ti n gbe lamẹrika, Andrew Dosummu  sinu kilaasi ọdun 2021.